Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 18:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀.

2. Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí.

3. Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’

4. Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan,

5. ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ”

6. Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí!

7. Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn?

8. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”

9. Ó wá pa òwe yìí fún àwọn tí wọ́n gbójú lé ara wọn bí olódodo, tí wọn ń kẹ́gàn gbogbo àwọn eniyan yòókù.

10. Ó ní, “Àwọn ọkunrin meji kan gòkè lọ sí Tẹmpili wọ́n lọ gbadura. Ọ̀kan jẹ́ Farisi, ekeji jẹ́ agbowó-odè.

11. “Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí.

12. Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’

13. “Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’

14. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”

Ka pipe ipin Luku 18