Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 15:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

2. Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.”

3. Jesu bá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní:

4. “Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan tí ọ̀kan sọnù ninu wọn, ṣé kò ní fi mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ ní pápá, kí ó wá èyí tí ó sọnù lọ títí yóo fi rí i?

5. Nígbà tí ó bá wá rí i, yóo gbé e kọ́ èjìká rẹ̀ pẹlu ayọ̀.

6. Nígbà tí ó bá dé ilé, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí aguntan mi tí ó sọnù.’

7. Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ayọ̀ tí yóo wà ní ọ̀run nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada ju ti ìtorí àwọn olódodo mọkandinlọgọrun-un tí kò nílò ìrònúpìwàdà lọ.

8. “Tabi, kí obinrin kan ní naira mẹ́wàá, bí ó ba sọ naira kan nù, ṣé kò ní tan iná, kí ó gbálẹ̀, kí ó fẹ̀sọ̀ wá a títí yóo fi rí i?

9. Nígbà tí ó bá rí i, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí owó tí mo sọnù.’

10. Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn angẹli Ọlọrun yóo máa yọ̀ nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada.”

11. Jesu ní, “Ọkunrin kan ní ọmọ meji.

12. Èyí àbúrò sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ogún tèmi tí ó tọ́ sí mi.’ Ni baba bá pín ogún fún àwọn ọmọ mejeeji.

Ka pipe ipin Luku 15