Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 12:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.

2. Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀.

3. Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀.

4. “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀!

Ka pipe ipin Luku 12