Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 11:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

2. Ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ máa wí pé,‘Baba, ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ.Kí ìjọba rẹ dé.

3. Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.

4. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè.Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”

5. Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta,

6. nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti ìrìn àjò dé bá mi, n kò sì ní oúnjẹ tí n óo fún un’;

Ka pipe ipin Luku 11