Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 10:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”

17. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrin pada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.”

18. Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀.

19. Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára.

20. Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.”

21. Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.

22. “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”

23. Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí,

24. nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.”

25. Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

26. Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”

27. Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”

Ka pipe ipin Luku 10