Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 7:3-18 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀.

4. Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í.

5. Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró.

6. Mo sọ èyí kí ẹ lè mọ̀ pé mo yọ̀ǹda fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ni; kì í ṣe pé mo pa á láṣẹ.

7. Ohun tí ìbá wù mí fun yín ni pé kí gbogbo eniyan rí bí mo ti rí; ṣugbọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun fún olukuluku yàtọ̀, ó fún àwọn kan ní oríṣìí kan, ó fún àwọn mìíràn ní oríṣìí mìíràn.

8. Mò ń sọ fún àwọn tí kò ì tíì gbeyawo ati fún àwọn opó pé ó dára fún wọn láti dá wà, bí mo ti wà.

9. Ṣugbọn bí wọn kò bá lè mú ara dúró, wọ́n níláti gbeyawo. Nítorí ó sàn kí wọ́n gbeyawo jù pé kí ara wọn máa gbóná nítorí èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin.

10. Mo ní ọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ti gbeyawo: ọ̀rọ̀ tèmi fúnra mi kọ́, bíkòṣe ti Oluwa wa. Aya kò gbọdọ̀ kọ ọkọ rẹ̀.

11. Bí ó bá kọ ọkọ rẹ̀, ó níláti dá wà ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ rẹ́, kí ó pada sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọkọ náà kò gbọdọ̀ kọ aya rẹ̀.

12. Mo ní ọ̀rọ̀ fún ẹ̀yin yòókù, (èrò tèmi ni o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oluwa wa.) Bí ọkunrin onigbagbọ kan bá ní aya tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu aya rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ọkọ má ṣe kọ̀ ọ́.

13. Bí obinrin onigbagbọ bá ní ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu ọkọ rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ó má ṣe kọ ọkọ rẹ̀.

14. Nítorí ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa aya rẹ̀, aya tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa ọkọ rẹ̀. Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, alaimỌlọrun ni àwọn ọmọ yín ìbá jẹ́ ṣugbọn nisinsinyii ẹni Ọlọrun ni wọ́n.

15. Ṣugbọn bí ẹni tí kì í ṣe onigbagbọ bá yàn láti fi ẹnìkejì tí ó jẹ́ onigbagbọ sílẹ̀, kí ó fi í sílẹ̀. Kò sí ọ̀ranyàn fún ọkọ tabi aya tí ó jẹ́ onigbagbọ ninu irú ọ̀ràn báyìí. Kí ẹ jọ wà ní alaafia ní ipò tí Ọlọrun pè yín sí.

16. Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là?

17. Kí olukuluku máa gbé ìgbé-ayé rẹ̀ bí Oluwa ti yàn án fún un, kí ó sì wà ní ipò tí ó wà nígbà tí Ọlọrun fi pè é láti di onigbagbọ. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń fi kọ́ gbogbo àwọn ìjọ.

18. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ ẹni tí ó kọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe pa ilà rẹ̀ rẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìkọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe kọlà.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 7