Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 6:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ?

8. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ!

9. Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin;

10. àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun.

11. Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.

12. Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí.

13. Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara.

14. Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀.

15. Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́!

16. Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.”

17. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí.

18. Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 6