Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 2:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará, nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ yín, n kò wá fi ọ̀rọ̀ dídùn tabi ọgbọ́n eniyan kéde àṣírí Ọlọrun fun yín.

2. Nítorí mo ti pinnu pé n kò fẹ́ mọ ohunkohun láàrin yín yàtọ̀ fún Jesu Kristi: àní, ẹni tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu.

3. Pẹlu àìlera ati ọpọlọpọ ìbẹ̀rù ati ìkọminú ni mo fi wá sọ́dọ̀ yín.

4. Ọ̀rọ̀ mi ati iwaasu mi kì í ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ó dùn létí yi yín lọ́kàn pada, iṣẹ́ Ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun ni mo fẹ́ fihàn;

5. kí igbagbọ yín má baà dúró lórí ọgbọ́n eniyan bíkòṣe lórí agbára Ọlọrun.

6. À ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún àwọn tí igbagbọ wọn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, kì í sìí ṣe ti àwọn aláṣẹ ayé yìí, agbára tiwọn ti fẹ́rẹ̀ pin.

7. Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa.

8. Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu.

9. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́,Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí,ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 2