Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 14:25-36 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”

26. Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ.

27. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ.

28. Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀.

29. Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ.

30. Bí ẹlòmíràn tí ó jókòó ní àwùjọ bá ní ìfihàn, ẹni kinni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níláti dákẹ́.

31. Gbogbo yín lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, lọ́kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kí gbogbo yín lè ní ìwúrí.

32. Àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ níláti lè káwọ́ ara wọn nígbà tí ẹ̀mí bá gbé wọn láti sọ àsọtẹ́lẹ̀.

33. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni.Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun,

34. àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí.

35. Bí nǹkankan bá wà tí wọ́n fẹ́ mọ̀, kí wọ́n bi àwọn ọkọ wọn ní ilé. Ìtìjú ni fún obinrin láti sọ̀rọ̀ ninu ìjọ.

36. Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kọ́ bẹ̀rẹ̀ ni àbí ẹ̀yin nìkan ni ẹ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun?

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 14