Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 14:17-34 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà.

18. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí mò ń sọ ọpọlọpọ èdè àjèjì ju gbogbo yín lọ.

19. Ṣugbọn ninu ìjọ, ó yá mi lára kí n sọ ọ̀rọ̀ marun-un pẹlu òye kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jù kí n sọ ọ̀rọ̀ kí ilẹ̀ kún ní èdè àjèjì lọ.

20. Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.

21. Ninu Òfin, ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Oluwa wí pé,“N óo bá àwọn eniyan yìí sọ̀rọ̀láti ẹnu àwọn eniyan tí ó ń sọ èdè àjèjì,ati láti ẹnu àwọn àlejò.Sibẹ wọn kò ní gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”

22. Àwọn èdè àjèjì yìí kì í ṣe àmì fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bíkòṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

23. Nítorí náà, nígbà tí gbogbo ìjọ bá péjọ pọ̀ sí ibìkan náà, tí gbogbo yín bá ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, tabi àwọn alaigbagbọ bá wọlé, ǹjẹ́ wọn kò ní sọ pé ẹ̀ ń ṣiwèrè ni?

24. Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ.

25. Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”

26. Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ.

27. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ.

28. Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀.

29. Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ.

30. Bí ẹlòmíràn tí ó jókòó ní àwùjọ bá ní ìfihàn, ẹni kinni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níláti dákẹ́.

31. Gbogbo yín lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, lọ́kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kí gbogbo yín lè ní ìwúrí.

32. Àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ níláti lè káwọ́ ara wọn nígbà tí ẹ̀mí bá gbé wọn láti sọ àsọtẹ́lẹ̀.

33. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni.Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun,

34. àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 14