Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 10:21-33 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ẹ kò lè mu ninu ife Oluwa tán kí ẹ tún lọ mu ninu ife ti ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè jẹ ninu oúnjẹ orí tabili Oluwa, kí ẹ tún lọ jẹ ninu oúnjẹ orí tabili ẹ̀mí burúkú.

22. Àbí a fẹ́ mú Oluwa jowú ni bí? Àbí a lágbára jù ú lọ ni?

23. Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá.

24. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.

25. Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́;

26. “Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

27. Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́.

28. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn.

29. Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà.Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi?

30. Bí mo bá jẹ oúnjẹ pẹlu ọpẹ́ sí Ọlọrun, ẹ̀tọ́ wo ni ẹnìkan níláti bá mi wí fún ohun tí mo ti dúpẹ́ fún?

31. Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun.

32. Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun.

33. Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 10