Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Kinni 1:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa.

3. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó máa wà pẹlu yín.

4. Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nígbà gbogbo nítorí yín, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fun yín ninu Kristi Jesu.

5. Nítorí pé ẹ ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn ninu Kristi: ẹ ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ sì tún ní ẹ̀bùn ìmọ̀.

6. Ẹ̀rí Kristi ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin yín,

7. tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹ̀bùn Ẹ̀mí kan tí ó kù tí ẹ kò ní. Ẹ wá ń fi ìtara retí ìfarahàn Oluwa wa Jesu Kristi,

8. ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi.

9. Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa.

10. Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀.

11. Nítorí pé ninu ìròyìn tí àwọn ará Kiloe mú wá, ó hàn sí mi gbangba pé ìjà wà láàrin yín.

12. Ohun tí mò ń wí ni pé olukuluku yín ní ń sọ tirẹ̀. Bí ẹnìkan ti ń wí pé. “Ẹ̀yìn Paulu ni èmi wà,” ni ẹlòmíràn ń wí pé. “Ẹ̀yìn Apolo ni èmi wà,” tí ẹlòmíràn tún ń wí pé, “Ẹ̀yìn Peteru ni mo wà ní tèmi.” Ẹlòmíràn sì ń wí pé, “Ẹ̀yìn Kristi ni èmi wà.”

13. Ṣé Kristi náà ni ó wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyìí? Ṣé èmi Paulu ni wọ́n kàn mọ́ agbelebu fun yín? Àbí ní orúkọ Paulu ni wọ́n ṣe ìrìbọmi fun yín?

14. Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu.

Ka pipe ipin Kọrinti Kinni 1