Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 8:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá,

11. ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó.

12. Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.

13-14. Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀.

15. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.”

16. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu.

17. Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀.

18. A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá.

19. Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn.

20. À ń ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni má baà rí nǹkan wí sí wa nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣe ètò ti ẹ̀bùn yìí.

21. Nítorí ète wa dára lójú Oluwa, ó sì dára lójú àwọn eniyan pẹlu.

22. A tún rán arakunrin wa tí a ti dánwò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ní ti ìtara rẹ̀ pé kí ó bá wọn wá. Nisinsinyii ó túbọ̀ ní ìtara pupọ nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé yín pupọ.

23. Ní ti Titu, ẹlẹgbẹ́ mi ati alábàáṣiṣẹ́ mi ni ninu ohun tí ó kàn yín. Ní ti àwọn arakunrin wa, òjíṣẹ́ àwọn ìjọ ni wọ́n, Ògo Kristi sì ni wọ́n.

24. Nítorí náà ẹ fi ìfẹ́ yín hàn sí wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn nǹkan tí a sọ fún wọn, tí a sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà nípa yín. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 8