Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 12:7-19 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga.

8. Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi.

9. Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé.

10. Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

11. Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki.

12. Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára.

13. Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí!

14. Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ.

15. Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi?

16. Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín.

17. Ninu àwọn tí mo rán si yín, èwo ni mo lò láti fi rẹ yín jẹ?

18. Mo bẹ Titu kí ó wá sọ́dọ̀ yín. Mo tún rán arakunrin wa pẹlu rẹ̀. Ǹjẹ́ Titu rẹ yín jẹ bí? Ṣebí Ẹ̀mí kan náà ni ó ń darí wa? Tabi kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni a jọ ń ṣiṣẹ́?

19. Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni.

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 12