Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kọrinti Keji 1:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Ìjọ Ọlọrun tí ó wà ní Kọrinti ati sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Akaya.

2. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.

3. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú,

4. ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi.

6. Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ.

7. Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà.

8. Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́.

9. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde.

10. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá,

11. bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa.

12. Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

13. Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀.

14. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé.

15. Nítorí ó dá mi lójú bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí ayọ̀ yín lè di ìlọ́po meji.

16. Ǹ bá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Masedonia, ǹ bá sì tún gba ọ̀dọ̀ yín lábọ̀. Ǹ bá wá ṣe ètò láti wá ìrànlọ́wọ́ fún ìrìn àjò mi sí Judia.

17. Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí. Ǹjẹ́ kò ní ìdí tí mo fi yí ètò yìí pada? Àbí ẹ rò pé nígbà tí mò ń ṣe ètò, mò ń ṣe é bí ẹni tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu kan náà tí mo fi pe “bẹ́ẹ̀ ni” ni n óo tún fi pe “bẹ́ẹ̀ kọ́?”

Ka pipe ipin Kọrinti Keji 1