Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 10:11-27 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.

12. Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká,

13. nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan.

14. Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí,

15. gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.

16. Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan.

17. “Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè.

18. Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19. Ìyapa tún bẹ́ sáàrin àwọn Juu nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

20. Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?”

21. Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù lè la ojú afọ́jú?”

22. Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu,

23. Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili.

24. Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.”

25. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi,

26. ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi.

27. Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi.

Ka pipe ipin Johanu 10