Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu 1:10-26 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n.

11. Ó wá sí ìlú ara rẹ̀, ṣugbọn àwọn ará ilé rẹ̀ kò gbà á.

12. Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.

13. A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn.

14. Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.

15. Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ”

16. Nítorí láti inú ẹ̀kún ibukun rẹ̀ ni gbogbo wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà kún oore-ọ̀fẹ́.

17. Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.

18. Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.

19. Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”

20. Ó sọ òtítọ́, kò parọ́, ó ní, “Èmi kì í ṣe Mesaya náà.”

21. Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?”Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.”Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?”Ó ní, “Èmi kọ́.”

22. Wọ́n bá tún bèèrè pé, “Ó dára, ta ni ọ́? Ó yẹ kí á lè rí èsì mú pada fún àwọn tí wọ́n rán wa wá. Kí ni o sọ nípa ara rẹ?”

23. Ó bá dáhùn gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti sọ pé:“Èmi ni ‘ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé:Ẹ ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Oluwa.’ ”

24. Àwọn Farisi ni ó rán àwọn eniyan sí i.

25. Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?”

26. Johanu dá wọn lóhùn pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ẹnìkan wà láàrin yín tí ẹ kò mọ̀,

Ka pipe ipin Johanu 1