Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Johanu Kinni 2:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.

2. Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu.

3. Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

4. Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀.

5. Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí

6. ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé.

7. Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.

8. Ṣugbọn ní ìdàkejì, òfin titun ni mò ń kọ si yín, èyí tí a rí òtítọ́ rẹ̀ ninu Jesu Kristi ati ninu yín, nítorí pé òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti ń tàn.

9. Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.

10. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, ohun ìkọsẹ̀ kò sí ninu olúwarẹ̀.

11. Ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀ wà ninu òkùnkùn; kò mọ ibi tí ó ń lọ, nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú.

12. Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu.

13. Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba.

Ka pipe ipin Johanu Kinni 2