orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 6 BIBELI MIMỌ (BM)

A Yan Àwọn Olùrànlọ́wọ́ Meje

1. Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ.

2. Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ.

3. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí.

4. Àwa ní tiwa, a óo tẹra mọ́ adura gbígbà ati iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ ìyìn rere.”

5. Ọ̀rọ̀ yìí dára lójú gbogbo àwùjọ, wọ́n bá yan Stefanu. Stefanu yìí jẹ́ onigbagbọ tọkàntọkàn, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n yan Filipi náà ati Prokoru ati Nikanọ ati Timoni ati Pamena ati Nikolausi ará Antioku tí ó ti gba ẹ̀sìn àwọn Juu.

6. Wọ́n kó wọn wá siwaju àwọn aposteli; wọ́n gbadura, wọ́n bá gbé ọwọ́ lé wọn lórí.

7. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ.

Àwọn Aṣiwaju Àwọn Juu Mú Stefanu

8. Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

9. Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn.

10. Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.

11. Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.”

12. Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀.

13. Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose.

14. Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.”

15. Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.