Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 26:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí.

16. Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́.

17. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí.

18. Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’

19. “Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá.

20. Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada.

21. Ìdí nìyí tí àwọn Juu fi mú mi ninu Tẹmpili, tí wọn ń fẹ́ pa mí.

22. Ṣugbọn Ọlọrun ràn mí lọ́wọ́. Títí di ọjọ́ òní mo ti dúró láti jẹ́rìí fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki. N kò sọ ohunkohun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn wolii ati Mose sọ pé yóo ṣẹlẹ̀.

23. Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.”

24. Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.”

25. Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 26