Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 23:3-21 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.”

4. Àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bá ní, “Olórí Alufaa Ọlọrun ni ò ń bú bẹ́ẹ̀?”

5. Paulu dáhùn pé, “Ará, n kò mọ̀ pé Olórí Alufaa ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ burúkú sí aláṣẹ àwọn eniyan rẹ.’ ”

6. Nígbà tí Paulu mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Sadusi ni apá kan ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ìgbìmọ̀, àtipé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Farisi ni àwọn mìíràn, ó kígbe pé, “Ẹ̀yin ará, Farisi ni mí. Farisi ni àwọn òbí mi. Nítorí ìrètí wa pé àwọn òkú yóo jí dìde ni wọ́n ṣe mú mi wá dáhùn ẹjọ́.”

7. Nígbà tí ó sọ báyìí, ìyapa bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Farisi ati àwọn Sadusi, ìgbìmọ̀ bá pín sí meji.

8. Nítorí àwọn Sadusi sọ pé kò sí ajinde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí angẹli tabi àwọn ẹ̀mí; ṣugbọn àwọn Farisi gbà pé mẹtẹẹta wà.

9. Ni ariwo ńlá bá bẹ́ sílẹ̀. Àwọn amòfin kan ninu àwọn Farisi dìde, wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, “Àwa kò rí nǹkan burúkú tí ọkunrin yìí ṣe. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀mí ni ó sọ̀rọ̀ fún un ńkọ́? Tabi angẹli?”

10. Nígbà tí àríyànjiyàn náà pọ̀ pupọ, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé kí wọn má baà fa Paulu ya. Ó bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun kí wọn wá fi agbára mú Paulu kúrò láàrin wọn, kí wọn mú un wọnú àgọ́ àwọn ọmọ-ogun lọ.

11. Ní òru ọjọ́ keji, Oluwa dúró lẹ́bàá Paulu, ó ní, “Ṣe ọkàn rẹ gírí. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ́rìí iṣẹ́ mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni o níláti jẹ́rìí nípa mi ní Romu náà.”

12. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Juu péjọ pọ̀ láti dìtẹ̀ sí Paulu. Wọ́n búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu.

13. Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ yìí ju bí ogoji lọ.

14. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà, wọ́n ní, “A ti jẹ́jẹ̀ẹ́, a sì ti búra pé a kò ní fẹnu kan nǹkankan títí a óo fi pa Paulu.

15. A fẹ́ kí ẹ̀yin ati gbogbo wa ranṣẹ sí ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé kí ó fi Paulu ranṣẹ sí yín nítorí ẹ fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ní tiwa, a óo ti múra sílẹ̀ láti pa á kí ó tó dé ọ̀dọ̀ yín.”

16. Ṣugbọn ọmọ arabinrin Paulu kan gbọ́ nípa ète yìí. Ó bá lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun, ó lọ ròyìn fún Paulu.

17. Paulu wá pe ọ̀kan ninu àwọn balogun ọ̀rún, ó ní, “Mú ọdọmọkunrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fún un.”

18. Balogun ọ̀rún náà bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun. Ó ní, “Ẹlẹ́wọ̀n tí ń jẹ́ Paulu ni ó pè mí, tí ó ní kí n mú ọdọmọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ yín nítorí ó ní ọ̀rọ̀ kan láti sọ fun yín.”

19. Ọ̀gágun náà bá fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀. Ó wá bi í pé, “Kí ni o ní sọ fún mi?”

20. Ọdọmọkunrin náà wá dáhùn pé, “Àwọn Juu ti fohùn ṣọ̀kan láti bẹ̀ yín pé kí ẹ mú Paulu wá siwaju ìgbìmọ̀ lọ́la kí àwọn le wádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní fínnífínní.

21. Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 23