Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 2:26-39 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí,sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí;

27. nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

28. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí,O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’

29. “Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní.

30. Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun,

31. ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé,‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú;bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’

32. Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí.

33. Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí.

34. Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run. Ohun tí Dafidi sọ ni pé,‘Oluwa wí fún oluwa mi pé:Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

35. títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di tìmùtìmù ìtìsẹ̀ rẹ.’

36. “Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!”

37. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?”

38. Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.

39. Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 2