Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 8:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀.

8. Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé,“Oluwa wí pé:Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.

9. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dání ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́,mo bá kẹ̀yìn sí wọn.

10. Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.

11. Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé,‘Mọ Oluwa.’Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí,ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki.

12. Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn,n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”

13. Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́.

Ka pipe ipin Heberu 8