Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 7:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu.

2. Abrahamu fún un ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun. Ní àkọ́kọ́, ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “ọba òdodo.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ́ ọba Salẹmu, èyí ni “ọba alaafia.”

3. Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo.

4. Ẹ kò rí bí ọkunrin yìí ti jẹ́ eniyan pataki tó, tí Abrahamu baba-ńlá wa fi fún un ní ìdámẹ́wàá àwọn nǹkan àṣàyàn ninu ìkógun rẹ̀.

5. Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu.

6. Ṣugbọn Mẹlikisẹdẹki tí kì í ṣe ìran Abrahamu gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì súre fún Abrahamu tí ó rí àwọn ìlérí Ọlọrun gbà.

7. Láìṣe àní-àní, ẹni tí ó bá tóbi ju eniyan lọ níí súre fún un.

8. Ati pé, àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gba ìdámẹ́wàá, ẹni tí yóo kú ni wọ́n. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ sọ nípa Mẹlikisẹdẹki pé ó wà láàyè.

9. A lè sọ pé nígbà tí Abrahamu san ìdámẹ́wàá, Lefi tí ń gba ìdámẹ́wàá náà san ìdámẹ́wàá,

10. nítorí a lè sọ pé ó wà ní ara Abrahamu baba-ńlá rẹ̀ nígbà tí Mẹlikisẹdẹki pàdé rẹ̀.

11. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni?

Ka pipe ipin Heberu 7