Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 12:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.

16. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀.

17. Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà.

18. Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́,

19. tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́.

20. Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!”

21. Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”

22. Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan,

23. ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé,

24. ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ.

25. Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.

26. Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.”

27. Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì.

Ka pipe ipin Heberu 12