5. Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á?
6. Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo,
7. kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu.
8. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.”
9. Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́.
10. A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.”
11. Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”
12. Ṣugbọn òfin kì í ṣe igbagbọ, nítorí a kà á pé, “Ẹni tí ó bá ń pa gbogbo òfin mọ́ yóo wà láàyè nípa wọn.”
13. Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.”
14. Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ.