Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 3:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba!

2. Nǹkankan péré ni mo fẹ́ bi yín: ṣé nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ fi gba Ẹ̀mí ni tabi nípa ìgbọràn igbagbọ?

3. Àṣé ẹ ṣiwèrè tóbẹ́ẹ̀! Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹlu nǹkan ti ẹ̀mí, ẹ wá fẹ́ fi nǹkan ti ara parí!

4. Gbogbo ìyà tí ẹ ti jẹ á wá jẹ́ lásán? Kò lè jẹ́ lásán!

5. Ṣé nítorí pé ẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ òfin ni ẹni tí ó fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fun yín ṣe fun yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí ó tún ṣiṣẹ́ ìyanu láàrin yín, tabi nítorí pé ẹ gbọ́ ìyìn rere, ẹ sì gbà á?

6. Bí Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ́, tí Ọlọrun wá gbà á gẹ́gẹ́ bí olódodo,

Ka pipe ipin Galatia 3