Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 1:8-24 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.

10. Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi.

11. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan.

12. Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí.

13. Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run.

14. Ninu ẹ̀sìn Juu, mo ta ọpọlọpọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ninu orílẹ̀-èdè mi yọ. Mo ní ìtara rékọjá ààlà ninu àṣà ìbílẹ̀ àwọn baba-ńlá mi.

15. Ṣugbọn nígbà tí ó wu Ọlọrun, tí ó ti yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi, ó fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ pè mí,

16. láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò,

17. n kò gòkè lọ sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ aposteli ṣiwaju mi, ṣugbọn mo lọ sí ilẹ̀ Arabia, láti ibẹ̀ ni mo tún ti pada sí Damasku.

18. Lẹ́yìn ọdún mẹta ni mo tó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rí Peteru, mo sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹẹdogun.

19. Kò tún sí ọ̀kan ninu àwọn aposteli yòókù tí mo rí àfi Jakọbu arakunrin Oluwa.

20. Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí pé kò sí irọ́ ninu ohun tí mò ń kọ si yín yìí!

21. Lẹ́yìn náà mo lọ sí agbègbè Siria ati ti Silisia.

22. Àwọn ìjọ Kristi tí ó wà ní Judia kò mọ̀ mí sójú.

23. Ṣugbọn wọ́n ń gbọ́ pé, “Ẹni tí ó ti ń fìtínà wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń waasu ìyìn rere igbagbọ tí ó fẹ́ parun nígbà kan rí.”

24. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun lógo nítorí mi.

Ka pipe ipin Galatia 1