Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 1:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia Ọlọrun, Baba wa, wà pẹlu yín ati ti Oluwa Jesu Kristi,

4. ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa,

5. ẹni tí ògo yẹ fún lae ati laelae. Amin.

6. Ẹnu yà mí pé ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípa oore-ọ̀fẹ́ Kristi, ẹ ti yára yipada sí ìyìn rere mìíràn.

7. Kò sí ìyìn rere mìíràn ju pé àwọn kan wà tí wọn ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n fẹ́ yí ìyìn rere Kristi pada.

8. Ṣugbọn bí àwa fúnra wa tabi angẹli láti ọ̀run bá waasu ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a ti waasu fun yín, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, mo tún ń wí nisinsinyii pé bí ẹnikẹ́ni bá waasu ìyìn rere mìíràn fun yín, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí olúwarẹ̀ di ẹni ègbé.

10. Ṣé ojurere eniyan ni mò ń wá nisinsinyii, tabi ti Ọlọrun? Àbí ohun tí ó wu eniyan ni mo fẹ́ máa ṣe? Bí ó bá jẹ́ pé ohun tí ó wu eniyan ni mò ń ṣe sibẹ, èmi kì í ṣe iranṣẹ Kristi.

11. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìyìn rere tí mò ń waasu kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ eniyan.

12. Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí.

13. Nítorí ẹ ti gbúròó ìwà mi látijọ́ nígbà tí mo wà ninu ẹ̀sìn ti Juu, pé mò ń fìtínà ìjọ Ọlọrun ju bí ó ti yẹ lọ. Mo sa gbogbo ipá mi láti pa á run.

Ka pipe ipin Galatia 1