Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanaya 3:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.”

14. Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó;ẹ̀yin ọmọ Israẹli!Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi,ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!

15. OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò,ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ.OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín;ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́.

16. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé:“Ẹ má ṣe fòyà;ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù.

17. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;yóo láyọ̀ nítorí yín,yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè

18. gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”OLUWA ní:“N óo mú ibi kúrò lórí yín,kí ojú má baà tì yín.

19. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,n óo gba àwọn arọ là,n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògogbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.

Ka pipe ipin Sefanaya 3