Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 9:14-26 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ bá gòkè wọ ìlú lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n rí Samuẹli tí ń jáde bọ̀ wá sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ wọn, ó ń lọ sí orí òkè tí wọ́n ti ń rúbọ.

15. Ó ku ọ̀la kí Saulu dé ni OLUWA ti sọ fún Samuẹli pé,

16. “Ní ìwòyí ọ̀la, n óo rán ọkunrin kan sí ọ láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. O óo ta òróró sí i lórí láti yàn án ní ọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Ọkunrin náà ni yóo gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, nítorí mo ti rí àwọn eniyan mi tí ń jìyà, mo sì ti gbọ́ igbe wọn.”

17. Nígbà tí Samuẹli fi ojú kan Saulu, OLUWA wí fún un pé, “Ọkunrin tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọ nìyí. Òun ni yóo jọba lórí àwọn eniyan mi.”

18. Saulu tọ Samuẹli lọ, lẹ́nu ibodè, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, níbo ni ilé aríran?”

19. Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín.

20. Nípa ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n sọnù láti ìjẹta, ẹ má da ara yín láàmú, wọ́n ti rí wọn. Ṣugbọn ta ni ẹni náà tí àwọn eniyan Israẹli ń fẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Ṣebí ìwọ ati ìdílé baba rẹ ni.”

21. Saulu dá a lóhùn, ó ní, “Inú ẹ̀yà Bẹnjamini tí ó kéré jù ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli ni mo ti wá, ati pé ìdílé baba mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Bẹnjamini. Kí ló dé tí o fi ń bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?”

22. Samuẹli bá mú Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn ńlá lọ, ó fi wọ́n jókòó sí ààyè tí ó ṣe pataki jùlọ níbi tabili oúnjẹ tí wọ́n fi àwọn àlejò bí ọgbọ̀n jókòó sí.

23. Ó sọ fún alásè pé kí ó gbé ẹran tí òun ní kí ó fi sọ́tọ̀ wá.

24. Alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ati itan ẹran náà wá, ó gbé e kalẹ̀ níwájú Saulu. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Wò ó, ohun tí a ti pèsè sílẹ̀ dè ọ́ ni wọ́n gbé ka iwájú rẹ yìí. Máa jẹ ẹ́, ìwọ ni a fi pamọ́ dè, pé kí o jẹ ẹ́ ní àkókò yìí pẹlu àwọn tí mo pè.”Saulu ati Samuẹli bá jọ jẹun pọ̀ ní ọjọ́ náà.

25. Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá sinu ìlú láti ibi ìrúbọ náà, wọ́n tẹ́ ibùsùn kan fún Saulu lórí òrùlé, ó sì sùn sibẹ.

26. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́, Samuẹli pe Saulu lórí òrùlé, ó ní, “Dìde kí n sìn ọ́ sọ́nà.” Saulu dìde, òun ati Samuẹli bá jáde sí òpópónà.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 9