Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 8:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba.

8. Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí.

9. Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”

10. Samuẹli bá sọ gbogbo ohun tí OLUWA bá a sọ fún àwọn tí wọ́n ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí àwọn.

11. Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 8