Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 8:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí àgbà dé sí Samuẹli, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.

2. Joẹli ni orúkọ àkọ́bí, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Abija. Beeriṣeba ni wọ́n ti ń ṣe adájọ́.

3. Ṣugbọn wọn kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere baba wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń dájọ́ èké.

4. Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama;

5. wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.”

6. Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA.

7. OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba.

8. Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí.

9. Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 8