Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 6:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Wọ́n gbé àpótí OLUWA sinu kẹ̀kẹ́ ẹrù náà, pẹlu àpótí tí wọ́n kó àwọn èkúté wúrà ati kókó ọlọ́yún wúrà náà sí.

12. Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.

13. Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.

14. Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

15. Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.

16. Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 6