Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 30:6-18 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.

8. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”

9. Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà.

10. Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.

11. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi,

12. èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn.

13. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.

14. A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.”

15. Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?”Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”

16. Ó mú Dafidi lọ bá wọn.Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda.

17. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ.

18. Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 30