Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 29:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli.

2. Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi.

3. Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?”Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4. Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 29