Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.