Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 28:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Dafidi dáhùn pé, “Ó dára, o óo sì rí ohun tí èmi iranṣẹ rẹ lè ṣe.”Akiṣi bá ní, òun óo fi Dafidi ṣe olùṣọ́ òun títí lae.

3. Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.

4. Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa.

5. Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ.

6. Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 28