Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 27:9-12 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi.

10. Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.”

11. Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia.

12. Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 27