31. o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.”
32. Dafidi dáhùn pé, “Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó rán ọ sí mi lónìí.
33. Ibukun ni fún ọ, fún ọgbọ́n tí o lò ati ohun tí o ṣe lónìí, tí o fà mí sẹ́yìn kúrò ninu ìpànìyàn ati ìgbẹ̀san.
34. OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.”
35. Dafidi gba ẹ̀bùn tí ó mú wá, ó sì sọ fún un pé, “Máa lọ sílé ní alaafia, kí o má sì ṣe bẹ̀rù, n óo ṣe ohun tí o sọ.”
36. Nígbà tí Abigaili pada dé ilé ó bá Nabali ninu àsè bí ọba. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó ti mu ọtí ní àmupara. Abigaili kò sì sọ nǹkankan fún un títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.
37. Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀ tán; Abigaili sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.
38. Ní ọjọ́ kẹwaa lẹ́yìn náà, OLUWA pa Nabali.
39. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.”Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ.