Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 21:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.

7. Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA.

8. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”

9. Ahimeleki sì dáhùn pé, “Idà Goliati ará Filistia tí o pa ní àfonífojì Ela nìkan ni ó wà ní ibí. A fi aṣọ kan wé e sí ẹ̀yìn efodu. Bí o bá fẹ́, o lè mú un. Kò sì sí òmíràn níbí lẹ́yìn rẹ̀.”Dafidi dáhùn pé, “Kò sí idà tí ó dàbí rẹ̀, mú un fún mi.”

10. Dafidi sá fún Saulu ní ọjọ́ náà. Ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

11. Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé:‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀,Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

12. Dafidi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ́kàn ó ṣe bí ẹni pé kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ṣugbọn ó bẹ̀rù Akiṣi, ọba Gati gidigidi.

13. Ó yí ìṣe rẹ̀ pada níwájú wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi wèrè. Ó ń fi ọwọ́ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà ààfin, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 21