Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 2:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Ẹ̀yin ọmọ mi, ọ̀rọ̀ burúkú ni àwọn eniyan OLUWA ń sọ káàkiri nípa yín.

25. Bí ẹnìkan bá ṣẹ eniyan, Ọlọrun lè parí ìjà láàrin wọn; ṣugbọn bí eniyan bá ṣẹ OLUWA, ta ni yóo bá a bẹ̀bẹ̀?”Ṣugbọn àwọn ọmọ Eli kò gbọ́ ti baba wọn, nítorí pé OLUWA ti pinnu láti pa wọ́n.

26. Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé.

27. OLUWA rán wolii kan sí Eli, kí ó sọ fún un pé, “Mo fara han ìdílé baba rẹ nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú Farao ọba ní ilẹ̀ Ijipti.

28. Ninu gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní Israẹli, ìdílé baba rẹ nìkan ni mo yàn láti jẹ́ alufaa mi, pé kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ alufaa níbi pẹpẹ, kí ẹ máa sun turari kí ẹ máa wọ ẹ̀wù efodu, kí ẹ sì máa wádìí nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo fún wọn ní gbogbo ẹbọ sísun tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí mi.

29. Kí ló dé tí o fi ń ṣe ojúkòkòrò sí ọrẹ ati ẹbọ tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn eniyan mi, tí o sì gbé àwọn ọmọ rẹ ga jù mí lọ; tí wọn ń jẹ àwọn ohun tí ó dára jùlọ lára ohun tí àwọn eniyan mi bá fi rúbọ sí mi ní àjẹyọkùn?

30. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí.

31. Wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí n óo run gbogbo àwọn ọdọmọkunrin ìdílé rẹ ati ti baba rẹ kúrò, débi pé kò ní sí àgbà ọkunrin kan ninu ìdílé rẹ mọ́.

32. Pẹlu ìbànújẹ́ ni o óo máa fi ìlara wo bí OLUWA yóo ṣe bukun Israẹli, kò sì ní sí àgbàlagbà ọkunrin ninu ìdílé rẹ mọ́ lae.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 2