Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 17:47-58 BIBELI MIMỌ (BM)

47. Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”

48. Bí Filistini náà ṣe ń bọ̀ láti pàdé Dafidi, Dafidi sáré sí ààlà ogun láti pàdé rẹ̀.

49. Dafidi mú òkúta kan jáde láti inú àpò rẹ̀, ó fi kànnàkànnà rẹ̀ ta òkúta náà, òkúta náà wọ agbárí Goliati lọ, ó sì ṣubú lulẹ̀.

50. Dafidi ṣẹgun Filistini náà láìní idà lọ́wọ́; kànnàkànnà ati òkúta ni ó fi pa á.

51. Dafidi sáré sí Goliati, ó yọ idà Goliati kúrò ninu àkọ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini rí i pé akikanju àwọn ti kú, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

52. Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda hó ìhó ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn Filistini lọ. Wọ́n lé wọn títí dé Gati ati dé ẹnu ibodè Ekironi. Àwọn Filistini tí wọ́n fara gbọgbẹ́ sì ṣubú láti Ṣaaraimu títí dé Gati ati Ekironi.

53. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli pada dé, wọ́n lọ kó ìkógun ninu ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.

54. Dafidi gbé orí ati ihamọra Goliati; ó gbé orí rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ṣugbọn ó kó ihamọra rẹ̀ sinu àgọ́ tirẹ̀.

55. Nígbà tí Saulu rí Dafidi tí ó ń lọ bá Goliati jà, ó bèèrè lọ́wọ́ Abineri, olórí ogun rẹ̀ pé, “Ọmọ ta ni ọmọkunrin yìí?”Abineri dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, n kò mọ̀.”

56. Ọba pàṣẹ fún un pé kí ó wádìí ọmọ ẹni tí ọmọ náà í ṣe.

57. Nígbà tí Dafidi pada sí ibùdó lẹ́yìn tí ó ti pa Goliati, Abineri mú un lọ siwaju Saulu, pẹlu orí Goliati ní ọwọ́ rẹ̀.

58. Saulu bi í léèrè pé, “Ọmọ, ta ni baba rẹ?”Dafidi dáhùn pé, “Ọmọ Jese ni mí, iranṣẹ rẹ, tí ń gbé Bẹtilẹhẹmu.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 17