Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 16:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”

2. Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.”OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni.

3. Pe Jese wá sí ibi ẹbọ náà, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ. N óo dárúkọ ẹnìkan fún ọ, ẹni náà ni kí o fi jọba.”

4. Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”

5. Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà.

6. Nígbà tí wọ́n dé, ó wo Eliabu, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú ẹni tí OLUWA yàn nìyí.”

7. Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”

8. Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 16