Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 15:21-32 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.”

22. Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ.

23. Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.”

24. Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.

25. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì mí, kí o sì bá mi pada, kí n lọ sin OLUWA níbẹ̀.”

26. Samuẹli dá a lóhùn pé, “N kò ní bá ọ pada lọ. O ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, OLUWA sì ti kọ ìwọ náà ní ọba Israẹli.”

27. Samuẹli bá yipada, ó fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn Saulu fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, ó sì ya.

28. Samuẹli bá wí fún un pé, “OLUWA ti fa ìjọba Israẹli ya mọ́ ọ lọ́wọ́ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ tí ó sàn jù ọ́ lọ.

29. Ọlọrun Ológo Israẹli kò jẹ́ parọ́, kò sì jẹ́ yí ọkàn rẹ̀ pada; nítorí pé kì í ṣe eniyan, tí ó lè yí ọkàn pada.”

30. Saulu dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀, ṣugbọn bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan mi ati gbogbo Israẹli. Bá mi pada lọ, kí n lọ sin OLUWA Ọlọrun rẹ.”

31. Samuẹli bá bá a pada, Saulu sì sin OLUWA níbẹ̀.

32. Samuẹli pàṣẹ pé kí wọ́n mú Agagi, ọba Amaleki wá, Agagi bá jáde tọ̀ ọ́ lọ pẹlu ìbàlẹ̀ ọkàn, ó ní, “Dájúdájú oró ikú ti rékọjá lórí mi.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 15