Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 13:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi.

12. Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.”

13. Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae.

14. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”

15. Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600).

16. Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, pẹlu àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pàgọ́ sí Geba ní agbègbè Bẹnjamini. Àgọ́ ti àwọn ará Filistia wà ní Mikimaṣi.

17. Àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà, mẹta ninu ọmọ ogun Filistini jáde láti inú àgọ́ wọn, àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Ofira ní agbègbè Ṣuali,

18. àwọn kan lọ sí apá ọ̀nà Beti Horoni, àwọn yòókù lọ sí ẹ̀bá ìpínlẹ̀ àtiwọ àfonífojì Seboimu ní ọ̀nà aṣálẹ̀.

19. Kò sí ẹyọ alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí pé àwọn ará Filistia ti pinnu pé, àwọn kò ní gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti rọ idà ati ọ̀kọ̀ fúnra wọn.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 13