Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 13:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Saulu jẹ́ bíi ọmọ ọgbọ̀n ọdún... nígbà tí ó jọba lórí Israẹli. Ó sì wà lórí oyè fún bíi ogoji ọdún.

2. Saulu yan ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin. Ó fi ẹgbaa (2,000) ninu wọn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Mikimaṣi, ní agbègbè olókè ti Bẹtẹli. Ẹgbẹrun (1,000) yòókù wà lọ́dọ̀ Jonatani, ọmọ rẹ̀, ní Gibea, ní agbègbè ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó bá dá àwọn yòókù pada sí ilé wọn.

3. Jonatani ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini tí wọ́n wà ní Geba; gbogbo àwọn ará Filistia sì gbọ́ nípa rẹ̀. Saulu bá fọn fèrè ogun jákèjádò ilẹ̀ náà, wí pé “Ẹ jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́ èyí.”

4. Gbogbo Israẹli gbọ́ pé Saulu ti ṣẹgun ọ̀wọ́ ọmọ ogun Filistini ati pé àwọn ọmọ Israẹli ti di ohun ìríra lójú àwọn ará Filistia. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá jáde láti wá darapọ̀ mọ́ Saulu ní Giligali.

5. Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.

6. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé ilẹ̀ ti ká àwọn mọ́, nítorí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini dùn wọ́n, wọ́n bá ń farapamọ́ káàkiri; àwọn kan sá sinu ihò ilẹ̀, àwọn mìíràn sì sá sinu àpáta, inú ibojì ati inú kànga.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 13