Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 8:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Dafidi ọba gbógun ti àwọn ará Filistia, ó ṣẹgun wọn, ó sì gba ìlú Mẹtẹgi-ama lọ́wọ́ wọn.

2. Ó ṣẹgun àwọn ará Moabu bákan náà, ó sì mú kí àwọn tí ó kó lẹ́rú ninu wọn dọ̀bálẹ̀ lórí ilẹ̀ ní ìlà mẹta, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà meji, ó sì dá àwọn tí wọ́n dọ̀bálẹ̀ lórí ìlà kan sí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Moabu ṣe di ẹrú rẹ̀, tí wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un.

3. Dafidi sì tún ṣẹgun Hadadeseri, ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí ó tí ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè odò Yufurate.

4. Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn.

5. Nígbà tí àwọn ará Siria dé láti Damasku tí wọ́n ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn.

6. Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

7. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí àwọn ọ̀gágun Hadadeseri fi ń jagun, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu.

8. Bákan náà, Dafidi ọba kó ọpọlọpọ idẹ láti Bẹta ati Berotai, ìlú meji ninu àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìjọba Hadadeseri.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 8