Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 7:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́

11. bíi ti ìgbà tí mo yan àwọn onídàájọ́ fún Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ OLUWA sì tún tẹnu mọ́ ọn fún un pé, ‘Èmi fúnra mi ni n óo sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé ńlá.

12. Nígbà tí ó bá jáde láyé, tí ó bá sì re ibi àgbà rè, n óo fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ jọba, n óo sì jẹ́ kí ìjọba rẹ̀ lágbára.

13. Òun ni yóo kọ́ ilé fún mi, n óo sì rí i dájú pé ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba títí laelae.

14. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ mi. Bí ó bá ṣẹ̀, n óo bá a wí, n óo sì jẹ ẹ́ níyà, bí baba ti í ṣe sí ọmọ rẹ̀.

15. Ṣugbọn n kò ní káwọ́ ìfẹ́ ńlá mi kúrò lára rẹ̀, bí mo ti ká a kúrò lára Saulu, tí mo sì yọ ọ́ lóyè, kí n tó fi í jọba.

16. Ìran rẹ kò ní parun, arọmọdọmọ rẹ ni yóo sì máa jọba títí ayé, ìjọba rẹ̀ yóo sì wà títí lae.’ ”

17. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA fi hàn án fún un.

18. Dafidi ọba bá wọlé, ó jókòó níwájú OLUWA, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Ìwọ OLUWA Ọlọrun! Kí ni mo jẹ́, kí ni ilé mi jámọ́ tí o fi gbé mi dé ipò yìí?

19. Sibẹsibẹ, kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, OLUWA Ọlọrun, o ti ṣèlérí fún èmi iranṣẹ rẹ nípa arọmọdọmọ mi, nípa ọjọ́ iwájú, o sì ti fihàn.

20. Kí ni mo tún lè sọ? O ṣá ti mọ̀ mí, èmi iranṣẹ rẹ, OLUWA Ọlọrun!

21. Nítorí ìlérí ati ìfẹ́ ọkàn rẹ ni o fi ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọnyi, kí iranṣẹ rẹ lè mọ̀ nípa wọn.

22. OLUWA Ọlọrun, o tóbi gan-an! Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, nítorí gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 7