Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 6:18-23 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí ó rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan náà ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

19. Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé.

20. Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!”

21. Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA.

22. Kékeré ni èyí tí mo ṣe yìí, n óo máa ṣe jù bí mo ti ṣe yìí lọ. N kò ní jẹ́ nǹkankan lójú rẹ, ṣugbọn àwọn iranṣẹbinrin tí o sọ nípa wọn yìí, yóo bu ọlá fún mi.”

23. Mikali, ọmọbinrin Saulu, kò sì bímọ títí ó fi kú.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 6